...fostering unity

among Yoruba people

...promoting the

teaching of Yoruba culture

...celebrating the

values of Yoruba

Ìpàdé Àpérò Ológójì Ọdún

Ọ̀RỌ̀ ÌKÍNI KÁÀBỌ̀ TÍ A KÀ NÍBI AYẸYẸ ÌSÍDE ÌPÀDÉ ÀPÉRÒ OLÓGÓJÌ ỌDÚN ẸGBẸ́ AKỌ́MỌLÉDÈ ÀTI ÀṢÀ YORÙBÁ NÀÌJÍRÍÀ TÍ Ó WÁYÉ NÍ FEDERAL GOVERNMENT COLLEGE ÒGBÓMỌ̀SỌ́, ÌPÍNLẸ̀ Ọ̀YỌ́ NÍ ỌJỌ́ AJÉ, ỌJỌ́ KẸRIN, OṢÙ KẸJỌ ỌDÚN 2014 LÁTI ẸNU ÀÀRẸ ẸGBẸ́ - ÀLÙFÁÀ AYỌ̀ ADÉṢÍNÀ

ỌLỌ́LÁ WA

SẸ́NÉTỌ̀ ABÍỌ́LÁ ADÉYẸMÍ AJÍMỌ̀BI

GÓMÌNÀ ÌPÍNLẸ̀ Ọ̀YÓ

Ọ̀JỌ̀GBỌ́N SOLOMON OLÁNÍYỌNU

KỌMÍSÁNNÀ ÈTÒ Ẹ̀KỌ́

ALÁGA ÀJỌ ÀWỌN OLÙKỌ́ SẸ́KÓŃDÍRÌ (TESCOM)

ALÁGA ÈTÒ ÈKỌ́́ KÁRÍAYÉ

KỌMÍṢÁNNÀ ÈTÒ ÀṢÀ ÀTI Ọ̀RỌ̀ ÌGBAFẸ́

OLÙBÁDÁMỌ̀RÀN GÓMÌNÀ LÓRÍ Ọ̀RỌ̀ ÀṢÀ

KÁBÍYÈSÍ, ṢỌ̀UN TÍ ÒGBÓMỌ̀ṢỌ́

GBOGBO Ẹ̀YIN ORÍADÉ YÒÓKÙ PÁTÁ TÓ WÀ NÍKÀLẸ̀

TÓTÓTÓ BÍ ARÓ

MO SÚN MỌ́BA NÍWỌ̀N EBÈ KAN

MO JÌNÀ SỌ́BA NÍWỌ̀N LÉBÈ MÉJÌ

N Ò JẸ́ RỌ́BA FÍN O

ARỌ́BA FÍN LỌBÁ PA

MÁ PA MÍ O, ỌBA Ẹ DÁKUN

ẸṢIN ỌBA YÓÒ JẸKO PẸ́

ÌRÙKẸ̀RẸ̀ YÓÒ LE SI

IGBA ỌDÚN ỌDÚN KAN

Ọ̀GÁ ILÉ IṢẸ́ ÌWÁDÌÍ ÀTI ÌDÀGBÀSÓKÈ ÈTÒ Ẹ̀KỌ́ (NERDC)

Ọ̀GÁ ILÉ IṢẸ́ TÓ Ń ṢÈTÒ ÌDÁNWÒ ONÍWÈÉ MẸ́WÀÁ (WAEC)

Ọ́GÁ ILÉ IṢẸ́ TÓ Ń ṢÈTÒ ÌDÁNWÒ ONÍWÈÉ MẸ́WÀÁ (NECO)

Ẹ̀YIN AGBÓHÙN SÁFẸ́FẸ́ ÀTI ONÍWÈÉ ÌRÒYÌN

Ẹ̀YIN ỌMỌ ẸGBẸ́ AKỌ́MỌLÉDÈ ÀGBÁÁLA AYÉ

Ẹ̀YIN Ọ̀RẸ́ WA GBOGBO

Ẹ̀YIN ẸGBẸ́ AMÚLÙÚDÙN YÒÓKÙ TÓ Ń LÉPA ÌDÀGBÁSÓKÈ ÀṢÀ ÀTI ÌṢE YORÙBÁ TÓ WÀ NÍBÍ TÍ N KÒ DÁRÚKỌ

AKỌ́MOÌ£LÉDEÌ€ – TIWA LAÌ€SÌ£AÌ€ OÌ£MOÌ£LÚAÌ€BÍ

AKỌ́MOÌ£LÁSÌ£AÌ€ – TIWA LEÌ€DEÌ€ OÌ£MOÌ£LÚAÌ€BÍ

A dúpẹ́ tí a ò yọ sọnù bíi ọmọ ọwọ̀

A dúpẹ́ tí a o kú sọ́nà bí èéfin

A dúpẹ́ o Èdùmàrè

Táráayé oÌ€ f’eÌ£gbẹ́ wa piÌ€taÌ€n láábi

EÌ£ jẹ́ kí gbogbo oÌ£moÌ£ EÌ£gbẹ́ ó fiÌ€baÌ€ f’ÉléduÌ€mareÌ€:

Kò sí ẹni tó ni gbogbo ọpẹ́ yìí bí ò bá jẹ́ Olódùmarè Ọba atẹ́nílẹgẹ́lẹgẹ́ fórí sagbeji, ọba alábẹ́nu àá sá sí, Ọba oníyẹ̀ẹ́ gbọ̀ọ̀rọ̀gbọọrọ. Ká bi ọ́ ò sí, ọba mímọ́. Mo ṣèbà o, mo ṣèbà gbogbo ènìyàn tí ń bẹ́ níkàlẹ̀. Ọ̀pọ̀ òjò ló ti rọ̀ tílẹ̀ ti fi mu, ṣùgbọ́n nínú Ẹgbẹ́ olókìkí yìí, Ẹgbẹ́ olóríire yìí, orin ọpẹ́ kò kúrò lẹ́nu wa, ìlù ọpẹ́ kò kúrò lọ́wọ́ wa, bẹ́ẹ̀ sì ni, ijó ẹpẹ́ kò kúrò lẹ́sẹ̀ wa.

 

Kì í ṣe pé àṣamọ̀ mí pọ̀, ohun tí ọ̀pọ̀ ọmọ Ẹgbẹ́ wa yìí mọ̀ ni, sùgbọ́n ó le ṣóòkùn sí ọ̀pọ̀ àwọn tó wà níkàlẹ̀. Ẹ dákun, ẹ jẹ́ kí n làá hàn yín bí bàtá tii ń ké lótù Ifẹ̀. Ọdún yìí ló pé ogójì ọdún tí Ẹgbẹ́ wa ti ń ṣe ìpàdé Àpérò àti ìpàdé Gbogbogboò. Ìdí nìyí tí inú gbogbo wa fi ń dùn, tí a tún wá fi aṣọ Àńkárá tí ẹ̀ ń wò lọ́rùn wa yìí sàmì ayẹyẹ ogójì ọdún náà. Ṣé ẹ wá rí i pé ọ̀rọ̀ wa tọ́pẹ́, ó ju ọpẹ́ lọ.

Akọ́mọlédè-------------

Akọ́mọláṣà-------------

 

A dúpẹ́ lọ́dọ̀ Adẹ́daÌ€á pé EÌ£gbẹ́ yiÌ€í ti kúroÌ€ lọ́moÌ£ iÌ€rákoÌ€roÌ€, ó ti kúroÌ€ lọ́moÌ£ aÌ€gbékọ́ruÌ€n roko. NÌ€jẹ́ iwájú tí aÌ€ ń loÌ£ náaÌ€, a koÌ€ ní di eÌ€roÌ€ ẹ̀hiÌ€n láéláé. Mo kí gbogbo aÌ€woÌ£n AÌ€aÌ€reÌ£ tó ti jeÌ£ sÌ£áájú mi, aÌ€woÌ£n gan-an ni aÌ€ bá máa peÌ€ ní eÌ€jiÌ€ká tí koÌ€ jẹ́ kí ẹ̀wuÌ€ ó bọ́ lọ́ruÌ€n. AÌ€woÌ£n ni aÌ€ti ránmú gángan EÌ£gbẹ́ yiÌ€í koÌ€ sÌ£ẹ̀yiÌ€n  eÌ€ékánná woÌ£n nípa iÌ€daÌ€gbaÌ€sókeÌ€ eÌ€deÌ€ aÌ€ti aÌ€saÌ€ YoruÌ€bá.

 

Bákan náà ni mo kàn sí gbogbo ọmọ Ẹgbẹ́ ní gbogbo àgbáyé fún akitiyan àti ìlàkàkà wọn lórí ṣíṣe ìdánilẹ́kọ̀ọ́ ni ìjọba ìbílẹ̀ àti ní ẹlẹ́kùnjẹkùn, lórí ìpàdé àpérò ẹlẹ́ẹ̀kan ní ọdún tí a máa ń ṣe, irú èyí tí a ń ṣe lọ́wọ́ yìí, àti nípàtàkì láti rí i pé èdè Yorùbá kò di àtẹ̀mẹ́rẹ̀ láàrin àwọn èdè àgbáyé. Ẹ ṣeun o.

 

Ẹgbẹ́ Akọ́mọlédè àti Àsà Yorùbá ti di igi àlọ́yè, ó ti di igi àràbà tí kò ṣe e fà tu, kò síbi tí ọwọ́jà kíkọ, kíkà àti lílò èdè Yorùbá kò dé ní gbogbo ayé. Èdè tó jẹ́ àtẹ́wọ́gbà gbáà ni. Mo sì ń fi àsìkò yìí kí gbogbo ọmọ káàárọ̀-o-ò-jíire àṣeyọrí yìí. A wá ń rọ àwọn Ẹgbẹ́ yòókù tí wọn ń tọpa ìdàgbàsókè àṣà, èdè àti ìṣe Yorùbá náà pé kí wọn wá darapọ̀ mọ́ wa kí á le túbọ̀ gbé èdè, àṣà àti ìṣe Yorùbá lárugẹ sí i.

 

Bí a sÌ£e pé biÌ€baÌ€ síbí lóniÌ€í yiÌ€í, ohun tí ń beÌ£ lọ́kaÌ€n kálukú koÌ€ joÌ£ ara woÌ£n. KoÌ€ sí eÌ£ni tí a ó bi tí koÌ€ ní rí wí. SuÌ€gbọ́n nnÌ€kan kan  tí yóoÌ€ papọ̀ juÌ€ ni wípé, mo wá kọ́ ẹ̀kọ́ mọ́ ẹ̀kọ́, mo siÌ€ wá ní iÌ€mọ̀ kún iÌ€mọ̀. IÌ€dí niÌ€yí tí aÌ€woÌ£n oÌ£moÌ£ iÌ€gbiÌ€mọ̀ AÌ€papọ̀ EÌ£gbẹ́ Akọ́moÌ£lédeÌ€ aÌ€ti AÌ€sÌ£aÌ€ YoruÌ€bá, NaÌ€iÌ€jiÌ€ríaÌ€ fi foríkorí, tí woÌ£n fikuÌ€nlukuÌ€n pé iÌ€mọ̀ aÌ€waÌ€ oluÌ€kọ́ gbọ́dọ̀ gboÌ€oÌ€roÌ€ sí i lórí aÌ€woÌ£n iÌ€wé LítírésÌ£ọ̀ gbogbo ti aÌ€joÌ£ WAEC aÌ€ti NECO yaÌ€n fún aÌ€woÌ£n oÌ£moÌ£, tí a fi jáde pẹ̀lú AÌ€koÌ€rí ‘AÌ€TÚPALẸ̀ AÌ€WOÌ£N IÌ€WÉ AÌ€SÌ£AÌ€YAÌ€N TÍ AÌ€JOÌ£ ASÌ£EÌ€DÁNWOÌ€ WAEC AÌ€TI NECO (2016 - 2020)’ ní oÌ£dún yiÌ€í. Ó dá mi lójú pé nígbaÌ€ tí a bá padaÌ€ délé, gbogbo aÌ€woÌ£n ohun tó yeÌ£ kí aÌ€woÌ£n oÌ£moÌ£ yiÌ€í moÌ€ lórí aÌ€woÌ£n iÌ€wé aÌ€saÌ€yaÌ€n wọ̀nyí ni a ó fi kọ́ woÌ£n tí woÌ£n yóoÌ€ fi yege.

 

ÀṢEYỌRÍ

OÌ£pẹ́ paÌ€taÌ€kiÌ€ lọ́wọ́ OÌ£ọ̀nirisÌ£aÌ€, OÌ£ba OkuÌ€nadé Síjúwadé OÌ£ọ̀ni ti Ilé-Ifẹ̀ fún sareÌ€ iÌ€lẹ̀ bíi mẹ́ta tí woÌ£n fún wa láti kọ́ ilé iÌ€yá EÌ£gbẹ́ wa. OÌ£ọ̀nirisÌ£aÌ€ mo kíi yín, eÌ£ ó pẹ́ fún wa, mo kí yín, eÌ£ o pẹ́ fún wa, a ó máaÌ€ rí yín bá o. AÌ€sÌ£eÌ£ a wa n fi aÌ€siÌ€koÌ€ yiÌ€í roÌ£ aÌ€wa oÌ£moÌ£ eÌ£gbẹ́ láti sowọ́pọ̀ kí eÌ£ gbaÌ€ruÌ€kuÌ€ tí wá láti leÌ€ kọ́ ilé sí orí ilẹ́ náaÌ€. Nmi kété¸tí a bá ti paÌ€rí aÌ€woÌ€rán ilé náaÌ€ ni yíyaÌ€, a nó sÌ£e iÌ€filọ́lẹ̀ náaÌ€ rẹ̀ lágbárá eÌ€duÌ€maÌ€reÌ€.

 

Ẹgbẹ́ akọ́mọlédè àti àṣà yorùbá tí dara pọ̀ mọ́ àwọn èdè míràn lágbàáyé tó ti fidìmúlẹ̀ láti máa ṣe ÀYÁJỌ́ ÈDÈ ABÍNIBÍ LÁGBÀÁYÉ. Ọdọọdún ni ayẹyẹ àyájọ́ yìí n gbòòreò sí i ni àwọn ìpínlẹ̀ wa gbogbo tí a sì n ṣe é tìlù-tìfọn. A n ṣe èyí kí èdè yorùbá nàá túnbọ jẹ́ ìtẹ́wọ́gbà láarin gbogbo ènìyàn àti pé kí èdè miràn máṣe jẹ gàbà lórí èdè wa.

 

Láti bi ogójì ọdún tí a ti n ṣe ìpàdé yìí a dúpẹ́ pé àkàlàmàgbò wa kò pan ọdún jẹ rí. A dúpẹ́ fún aṣeyọrí yìí. Ọmọ ogóji ọdún kìí ṣe ọmọdé mọ́. Àṣeyọrí ńlá ni fún wa pé ẹgbẹ́ yìí kò yọ sọnù bíi ọmọ ọwọ̀. Ìfẹ́ àti ìrẹ́pọ̀ tó jọba láàrin wa kò lẹ́gbẹ́. Àdúrà wa ni pé Ẹgbẹ́ yìí yóò máa dàgbàsókè síi. Ewé ńlá wa kò ní padà rú wẹ́wẹ́ mọ́ láéláé. Àṣe.

 

IÌ€SÌ£OÌ€RO

A dára má kù síbìkan kò sí, òun la fẹ́ wí, ìṣòro ńlá ló ń dojúkọ ẹ̀kọ́-èdè Yorùbá ní orílẹ̀-èdè yìí bẹ̀rẹ̀ láti àwọn ilé-ẹ̀kọ́ alákọ̀ọ́bẹ̀rẹ̀ títí dé ilé-ẹ̀kọ́ sẹ́kọ́ńdìrì àgbà. Àìkọbiara ìjọba àpapọ̀ sí àwọn èdè abínibí ni ilẹ̀ wa lórí ẹ́kọ́ lo n jẹ́ kí ọ̀pọ̀ àwọn ipínlẹ́ ó máa fi ọwọ́ yẹpẹrẹ mú un. Ìlànà ètò ẹ̀kọ́ tí wọn ṣe ní ọdún 1976 ti wọ́n ṣe àtúnkọ rẹ̀ ní ọdún 1981 lá à kalẹ̀ pé ọ̀kan nínú èdè abínibí mẹ́tẹ̀ẹ̀ta tí èdè Haúsá, èdè Ìgbò, àti èdè Yorùbá jẹ ọ̀ràn-an-yàn fún akẹ́kọ̀ọ́ jáde ilé-ẹ̀kọ́ sẹ́kọ́ńdírì àgbà. Èyí kò rí bẹ́ẹ̀ mọ́, ìjọba kò sì sọ̀rọ̀ mọ́, àjọ tó ń ṣe ìwádìí àti ìdàgbàsókè ẹ̀kọ́ (NERDC) tó jẹ́ ẹ̀ka kan lábẹ́ ilé-iṣẹ́ ètò ẹ̀kọ́ ti ìjọba àpapọ̀ tún ń lo idà tirẹ̀ tí kò jẹ́ kí a le mọ́ odó tí a dọ̀rúnlá sí lórí àwọn èdè abínibí wa ní àwọn ilé-ẹ̀kọ́ wa gbogbo. Àwọn òbí ò fi èdè Yorùbá bá àwọn ọmọ sọ̀rọ̀ mọ́. Èdè gẹ̀ẹ́sì ni wọ́n ń lò ní gbogbo ìgbà. Èyí ni pé ọ̀pọ̀ àwọn òbí yìí ní wọ́n pa àmì ìdánimọ̀ wa rẹ́ gẹ́gẹ́ bíi ọmọ Yorùbá nítorí pé èdè jẹ́ àmì pàtàkì tí a fi ń dá ẹ̀yà kan mọ̀. Há a, ẹ̀yin ọmọ Yorùbá o, ẹ máṣe jẹ́kí á mú ara wa lẹ́rú lẹ́ẹ̀kejì o. Ẹ gbé èdè yìí lárugẹ. Bí a bá fojú wò ó, kò sí ohun tó ń jẹ́ òwe lẹ́nu àwọn ọmọ. Àlọ́ àpamọ̀ àti àpagbè ti di ohun ìgbàgbé. Agídí làwọn ọmọ fi ń kọ́ èdè Yorùbá láwọn ilé-ẹkọ́ wa gbogbo. Ìjọba kò sì fi bẹ́ẹ̀ gba àwọn olùkọ́ èdè Yorùbá ṣíṣẹ́. Níbo la wá ń lọ lórí àtijẹ́ kí èdè wa ó le túbọ̀ gbèrú sí i?

 

A wá ń késí gbogbo ẹ̀yin tí ẹ nífọ̀n-léèkánná láti bá wa rawọ́ ẹ̀bẹ̀ sí àwọn ìjọba wa gbogbo kí wọ́n má jẹ́ kí èdè Yorùbá ó di ohun ìgbàgbé. Yorùbá ló ni Àsà àti ìse, à ń rọ àwọn orí Adé wa gbogbo láti jáwọ́ nínú à ń sọ èdè Gẹ̀ẹ́sì níbi ìpàdé wọn gbogbo. Ó ṣeeṣée láti wá ògbufọ̀ tí yóò máa bá yín gba ọ̀rọ̀ yín sọ sí èdè Gẹ̀ẹ́sì tí ẹ bá gba àlejò láàfin yín, kì í ṣe àìgbọ́ èdè Gẹ̀ẹ́sì yín la fi dá àbá yìí, ṣùgbọ́n kí èdè wa má ba à kú la fi sọ́. Àwọn ìjọba wa pàápàá gbọ́dọ̀ máa ṣe àmúlò èdè yìí níbi ìpàdé wọn gbogbo nítorí ìwọ̀nba èdè Gẹ̀ẹ́sí ni wọ́n sọ fáwọn aráàlú nígbà tí wọn ń tọ̀rọ̀ ìbò. È̀dè yìí ò gbọdọ̀ kú o.

 

Ẹgbẹ́ yìí ní ìsòro owó púpọ̀ ọ̀pọ̀, iṣẹ́ ní a fẹ́ ṣe láti mú kí ẹgbẹ́ yìí tẹ̀síwájú, sùgbọ́n àìsí owó ń já wa ní tànmọ́nọ̀n pàápàá láti kọ́ ilé Ìyá Ẹgbẹ́ wa lórí ilẹ̀ wa ni Ifẹ̀. Mo wá ń lo àsìkò yìí láti pàrọwà sí àwọn ọmọ Ẹgbẹ́ láti san gbogbo owó tó yẹ kí á san nínú ìpàdé yìí. Bákan náà ni mò ń bẹ àwọn bàbá wa Kábíyèsí - Àwọn Orí Adé wa gbogbo láti bá wa kàn sí àwọn ọmọ ìlú wọn gbogbo tí orí ṣẹ́gi ọlà fún, tí wọn sì ní ìfẹ́ èdè Yorùbá láti ṣe àtìlẹyìn owó fún Ẹgbẹ́ yìí àti pàápàá sí àwọn Gómìnà wa gbogbo ní Ìjọba Ìwọ̀ Oòrùn Nàìjíríà.

 

IÌ€DÚPẸ́                                                                   

Lẹ́ẹ̀kan síi, mo dúpẹ́ lọ́wọ́ Gómìnà Ìpínlẹ̀ Ọ̀yọ́, Ọlọ́lá Ajímọ̀bí àti àwọn ikọ̀ wọn pé wọ́n gbà wá láàyè láti ṣe ìpàdé Àpérò wá tí ọdún yìí ní Ìpínlẹ̀ wọn. A dúpẹ́ o, a ó máa ríi yín bá o. Ẹrù Ìpínlẹ̀ Ọ̀yọ́ tí ẹ rù, Adẹ́ẹ̀dá yóò bá yín gbé e dórí, kò sí ni yẹ̀ ẹ́ lẹ̀.

 

Bákan náà ní ọpẹ́ mi tún lọ sọ́dọ̀ Bàbá wa Ṣọ̀un tí Ògbómọ̀sọ́ pẹ̀lú àwọn orí Adé gbogbo tó wá yẹ́ wa sí lónìí. A dúpẹ́ fún gbígbà tí ẹ gbà wá tọwọ́-tẹsẹ̀. Adé á pẹ́ lórí, bàtà á pẹ́ lẹ́sẹ̀, ìrùkẹ̀rẹ̀ á di abẹ́rẹ́, ẹṣin ọba á jẹ oko pẹ́, àṣẹ á pẹ́ lẹ́nu kánrin-kése.

Mo fẹ́ lo àsìkò yìí láti dúpé lọ́wọ́ ọ̀gá ilé-ẹ̀kọ́ yìí fún àyè tí wọ́n fún wa láti ṣe ìpàdé àpérò yìí ni ilé-ẹkọ́ yìí ìmọ́lẹ̀ ilé-ẹ̀kọ́ yìí kò ní wọ òòkùn.

 

Ọpẹ́ pàtàkì lọ́wọ́ àwọn ilé-iṣẹ́ atẹ̀wétà, Macmillan, Evans, University Press, Learn Africa, Rasmed, Extension, Spectrum, abbl fún ìrànlọ́wọ́ àti àtìlẹyìn àtìgbàdégbà tí ẹ ń ṣe fún ẹgbẹ́ yìí. Ẹyẹ kìí fò kí ó forí sọgi, ìkọ́ kìí kọ́ ejò lọ́nà, òkè ní ẹ́ máa lọ o, àṣẹ. Ara ìwúrí tí ẹ ń ṣe fún Ẹgbẹ́ ló mú kí á rò pé kí á fi àmì ẹ̀yẹ dá yín lọ́lá lónìí láti fi sàmì àyẹyẹ ìpàdé Àpérò ológójì ọdún tí à ń ṣe lónìí. Ilé-iṣẹ́ yín gbogbo yóò máa gbèrú sí i. Àṣẹ.

 

Mo tún dúpẹ́ lọ́wọ́ àwọn ọmọ Ìgbìmọ̀ Ẹgbẹ́ Akọ́mọlédè lápapọ̀, ní pàtàkì jùlọ àwọn ọmọ Ìgbìmọ̀ Ẹgbẹ́ yìí ní ìpínlẹ̀ wa gbogbo àti ní ìpínlẹ̀ yìí fún ìlàkàkà wọn tó mú kí ìpàdé yíì ó dùn tó sì lárinrin. N kò ní sàì dúpẹ́ lọ́wọ́ ẹ̀yin ìrírí dọgbọ́n wa gbogbo, ẹ̀yin àgbà Ẹgbẹ́, àti ẹ̀yin olùbádàmọ̀ràn Ààrẹ Ẹgbé yìí. Ẹ ṣeun-un o, iwájú ni ojúgun ń gbé, iwájú lẹ ó máa lọ.

 

ÌGÚNLẸ̀

Ní àkótán, mo kí gbogbo ọmọ Ẹgbẹ́ pé a kú ọdún, a kú ìyèdún, ẹ̀mí á ṣe púpọ̀ rẹ̀ lókè eèpẹ̀. A sì kú àpérò. Ẹ jẹ́ kí ẹ̀mí ìṣọ̀kan, ìgbọ́ra-ẹni-yé, àti ìfaradà ó jọba lọ́kàn gbogbo wa. Ẹ jẹ́ ká fí ara wa ṣe òṣùsù ọwọ̀ lásìkò ìpàdé yìí àti lẹ́yìn ìpàdé, kí á ba à lé jẹ́ àwòkọ́ṣe fún gbogbo àwọn Ẹgbẹ́ mìíràn. Kí a sì fi ara balẹ̀ láti gbọ́ gbogbo ìdánilẹ́kọ̀ọ́ wa.

 

Ẹ ṣeun o

Mo dúpẹ́ fún sùúrù yín látàárọ̀

Ojú wa yóò máa rọ́dún o, nítorí pé:

Ọdọọdún nilá ń sogún

Ọdọọdún ni àwọn nkàn

Ń so lọ́gbọ̀n-lọ́gbọ̀n

Ẹgbẹ́ wa ò ní pọ̀ ìpọ̀ àìṣí èrè

Àkàlàmàgbò wa kò ní pọdún jẹ

Àṣèyí ṣàmọ́dún láṣẹ Èdùmàrè

Akọ́moÌ£lédeÌ€ – Tiwa laÌ€sÌ£aÌ€ OÌ£moÌ£lúaÌ€bí

Akọ́moÌ£lásÌ£aÌ€ – Tiwa leÌ€deÌ€ OÌ£moÌ£lúaÌ€bí.

 

--------------------------------------------------------------------------------------------------------------------------------------------

Ọ̀RỌ̀ ÌKÍNI KÚ ÀBỌ̀ SÍBI AYẸYẸ ÀJỌ̀DÚN OGÓJÌ ỌDÚN ÀTI ÌPÀDÉ ÀPÉRÒ ỌLỌ́DỌỌDÚN TI ẸGBẸ́ AKỌ́MỌLÉDÈ ÀTI ÀṢÀ NÍ ORÍLẸ̀-ÈDÈ NÀÌJÍRÍÀ, TÍ Ó WÁYÉ NÍ ILÉ Ẹ̀KỌ́

“FEDERAL GOVERNMENT COLLEGE” OÌ€GBÓMỌ̀SÌ£Ọ́,

NÍ ỌJỌ́ KẸTA SÍ ỌJỌ́ KEJE, OṢÙ KẸJỌ, ỌDÚN 2014

LÁTI ẸNU DÍÁKÓNÌ MATTHEW KỌ́LÁWỌLÉ ÒGÚNKÚNLÉ

(ALÁGA ÌPÍNLẸ̀ Ọ̀YỌ́)

  • Mo kí OÌ£lọ́lá Sẹ́nátọ̀ Abíọ́lá AdéyeÌ£mí Ajímọ́bi (GómiÌ€naÌ€ IÌ€pínlẹ̀ Ọ̀yọ́), 
  • AÌ€aÌ€reÌ£ EÌ£gbẹ́, AÌ€luÌ€fáaÌ€ Ayọ̀ AdésínaÌ€,
  • AbeÌ£nugan Ilé IÌ€gbímọ́  AsÌ£oÌ€fin; MoÌ£nsurat Aya SuÌ€nmọ́nuÌ€;
  • KoÌ£mísánnaÌ€ náaÌ€ fún EÌ€toÌ€ Ẹ̀kọ́ ní Ọ̀yọ́, Ọ̀jọ̀gbọ́n Solomon OÌ£láníyoÌ£nu;
  • Orí Adé, OÌ£ba AláyélúwaÌ€; OÌ£ba JimoÌ£h OÌ£láduÌ€nní OyeÌ€wuÌ€mí Ajagungbadé III (JP) CON. Sọ̀ún ti Ilẹ̀ Ò́gbómọ̀sÌ£ọ́.
  • Alága IÌ€joÌ£ba IÌ€bílẹ̀ ATISBO, AmoÌ€fin Jacob, Fúnmi OÌ€gúnmọ́lá,
  • OluÌ€sọ̀rọ̀ PaÌ€taÌ€kiÌ€ OÌ€jÌ£ọ̀gbọ́n Dúró AdélékeÌ€,
  • Gbogbo ẹ̀yin AÌ€lejoÌ€ paÌ€taÌ€kiÌ€ paÌ€taÌ€kiÌ€,
  • Gbogbo oÌ£moÌ£ iÌ€gbiÌ€mọ̀ aÌ€papọ̀ EÌ£gbẹ́
  • OÌ£moÌ£ eÌ£gbẹ́ Akọ́moÌ£lédeÌ€ aÌ€ti AÌ€sÌ£a káaÌ€kiri Orílẹ̀ – EÌ€deÌ€ NaÌ€iÌ€jíríaÌ€,
  • Gbogbo oÌ£moÌ£ EÌ£gbẹ́ ní IÌ€pínlẹ̀ Ọ̀yọ́.

Mo kí wa kú àbọ́ sí ìpàdé àpérò ti ọdún yìí. A kú ọjọ́ méji, jọ mẹ́ta, ilé ò dáa bí? Ọ̀dẹ̀dẹ̀ ò sunwọ̀n? Ẹni tí a bí tilẹ́ ti rí ní ìta tó ń jó; ilé dára tàbí kò dàra ti kúrò lọ́rọ̀ onítọ̀hún yẹn; ilé wa yóò máa rójú, ọ̀ọ̀dẹ̀ wa yóò máa tòrò; ilé tó sì dára tí a fi sílẹ̀, àìrójú kò ní wọlé ọ̀hún lẹ́yìn wa.

 

OÌ£jọ́ ọ̀hún náaÌ€ niÌ€yí bí aÌ€ná yiÌ€í, tí a fi eÌ£gbẹ́ yiÌ€í lọ́lẹ̀ ní nnÌ€kan bíi OgójiÌ€ Odún ó lé máruÌ€n-ún sẹ́yiÌ€n lábẹ́ AÌ€aÌ€reÌ£ aÌ€kọ́kọ́;  OlóyeÌ€ Akínbọ̀wálé ní íluÌ€ IÌ€baÌ€daÌ€n, ní IÌ€pínlẹ̀ Ọ̀yọ́, tí a siÌ€ sÌ£e aÌ€péroÌ€ aÌ€kọ́kọ̀ ni OgójiÌ€ oÌ£dún sẹ́yiÌ€n ní IÌ€pínlẹ̀ Ọ̀yọ́ yiÌ€í náa. Ó yeÌ£ kí á kíra wa kú oríire wí pé, eÌ€sÌ£o wóró músítádiÌ€ tí aÌ€woÌ£n baÌ€bá yiÌ€í gbín lọ́jọ́ náaÌ€. AÌ€woÌ£n bíi OlóyeÌ€ E.D. Akínbọ̀wálé, AlaÌ€gbaÌ€ Adétúnjí; Ọ̀jọ̀gbọ́n OÌ£mọ́táyọ̀ aya OlútóyeÌ€, OloÌ€oÌ€gbé AÌ€laÌ€ájiÌ€ OyeÌ€bánjí Mustapha, OlóyeÌ€ Délé AÌ€jaÌ€yi, Ọ̀jọ̀gbọ́n OlúgbóyeÌ€ga AÌ€laÌ€bá, Ọ̀mọ̀wé Adémọ́lá, OÌ£dẹ́tókun aÌ€ti aÌ€woÌ£n aÌ€gbaÌ€ eÌ£gbẹ́ tó ti suÌ€n aÌ€ti aÌ€woÌ£n tó siÌ€ waÌ€ láyé ló di igi AÌ€raÌ€baÌ€ lóniÌ€í yiÌ€í o; EÌ£ oÌ€ siÌ€ tún ríiÌ€ bí iÌ€taÌ€n koÌ€ sÌ£e sÌ£e oÌ€jóóró; nígbaÌ€ tí a ó tún sÌ£e ayeÌ£yeÌ£ OgójiÌ€ OÌ£dun, IÌ€pínlẹ̀ Ọ̀yọ́ náaÌ€ ló tún bọ́ sí; A dúpẹ́ lọ́wọ́ OÌ£lọ́run OÌ£ba.

 

Mo bá GómiÌ€naÌ€ Olóríire wa ní Ípínlẹ̀ Ọ̀yọ́ yọ̀ wí pé aÌ€woÌ£n nnÌ€kan iÌ€taÌ€n málegbaÌ€gbé ló ń sÌ£eÌ£lẹ̀ ni akókoÌ€ tiwoÌ£n. Mo rántí pé láiÌ€pẹ́ yiÌ€í náaÌ€ ni wọ́n gba aÌ€lejoÌ€ gbogbo aÌ€woÌ£n ọ̀gá Ilé-ẹ̀kọ́ Sẹ́kọ́ńdíriÌ€ kaÌ€aÌ€kiri Orílẹ̀-eÌ€deÌ€ NaÌ€iÌ€jíríaÌ€ ní iÌ€lú IÌ€baÌ€daÌ€n. Ní aÌ€siÌ€koÌ€ tíwoÌ£n ni iÌ€joÌ£ Onítẹ̀boÌ£mi ní Orílẹ̀ – eÌ€deÌ€ NaÌ€iÌ€jíríaÌ€ sÌ£e ayeÌ£yeÌ£ OÌ£gọ́ruÌ€n-ún OÌ£dún ní ilú IÌ€baÌ€daÌ€n, fún iÌ€gbaÌ€ aÌ€kọ́kọ́, aÌ€siÌ€koÌ€ woÌ£n ni OlúbaÌ€daÌ€n ti ilẹ̀ IÌ€baÌ€daÌ€n pé OÌ£gọ́rún-ún oÌ£dún tí wọ́n siÌ€ sÌ£e ayeÌ£yeÌ£ rẹ̀ ní IÌ€baÌ€daÌ€n; A oÌ€ fi wọ́n sÌ£e eÌ£loÌ€míraÌ€n lóniÌ€í, tí woÌ£n tún ń fojú rí ayeÌ£yeÌ£ OgójiÌ€ oÌ£dún tí eÌ£gbẹ́ Akọ́moÌ£lédeÌ€ aÌ€ti AÌ€sÌ£aÌ€ ní Orílẹ́-eÌ€deÌ€ NaÌ€iÌ€jíríaÌ€ ní Ilú OÌ€gbómọ̀sọ́. Oríire náaÌ€ yóoÌ€ máa tẹ̀síwájú.

Ẹyin Ọmọ ẹgbẹ́ lápapọ̀; Ọ̀kan nínú ìdí pàtàkì tí a fi pe Abẹnugan Ilé Ìgbìmọ̀ Aṣòfin Ìpínlẹ̀ Ọ̀yọ́ wá síbí láti yẹ́ wọn sí ni wí pé;

  1.  NígbaÌ€ tí iÌ€joÌ£ba aÌ€papọ̀ gbé aÌ€bá kan diÌ€dé nínú eÌ€toÌ€ ẹ̀kọ́ wí pé, EÌ€deÌ€ YoruÌ€bá koÌ€ jẹ́ kaÌ€n-ń-pá fún aÌ€woÌ£n asÌ£eÌ€dánwoÌ€ WASCE aÌ€ti NECO mọ́, Ilé IÌ€gbiÌ€mọ̀ AsÌ£oÌ€fin iÌ€pínlẹ̀ Ọ̀yó, lábẹ́ iÌ€daríi GómínaÌ€ wa ni ó kọ́kọ́ ta koÌ€ó, tí wọ́n si soÌ£ọ́ di oÌ€fin ní IÌ€pínlẹ̀ Ọ̀yọ́ wí pé, gbogbo asÌ£eÌ€gánwoÌ€ WASCE aÌ€ti NECO yálaÌ€ ní Ilé-Ẹ̀kọ́ Sẹ́kọ́ndírí tí IÌ€joÌ£ba taÌ€bí ti AládaÌ€ni gbọ́dọ́ máa sÌ£e EÌ€deÌ€ YoruÌ€bá.
  2. Wọ́n pa láṣẹ wí́ pé gbogbo ọmọ tí yóò bá gba iṣẹ́ ní Ìpínlẹ̀ Ọ̀yọ́ ní ọjọ́ iwàjù gbọ́dọ̀ ṣe àṣeyege nínú èdè Yorùbá.
  3. Wọ́n fi kún un pé ní gbogbo Ọjọ́ rú, èdé Yorùbá ni gbogbo Ilé-èkọ́ ní Ìpínlẹ̀ Ọ̀yọ́ gbọ́dọ̀ máa fi kọ Orin orílẹ̀-èdè wa àti kíka ẹ̀jẹ́.
  4. Ilé Ìgbìmọ̀ aṣofin Ìpínlẹ̀ Ọ̀yọ́ gan-an yóó máa lo èdè Yorùbá fún gbogbo ètò wọn nílé ìgbìmọ̀ aṣòfin ó kéré jù, ẹ̀ẹ̀kan lóṣẹ̀.
  5. Bí ẹ wo ìwọṣọ Gómínà wa; Àwọn ọmo ilé ìgbìmọ̀ aṣofin àti gbogbo àwọn tí ń sètò ìjọba ní ìpínlẹ̀ Ọ̀yọ́, ti Ọmọlúàbí ni.

 

Ẹ̀yin aÌ€gbaÌ€ leÌ£ soÌ£ pé, “iÌ€reÌ€ere tó ń jó lójú omi, OníluÌ€ú rẹ̀ waÌ€ nísaÌ€lẹ̀ odoÌ€” yaÌ€tọ̀ sí wí pé ArábiÌ€nrín yiÌ€í ni ObiÌ€nrin aÌ€kọ́kọ́ tí yóó darí ilé iÌ€gbiÌ€mọ̀ asÌ£ofin ní iÌ€pínlẹ̀ Ọ̀yọ́. OÌ€un náaÌ€ ni atọ́kuÌ€n aÌ€laÌ€áfíaÌ€ nínú ilé iÌ€gbiÌ€moÌ€ asÌ£oÌ€fin torí pé láti iÌ€gbaÌ€ tí iÌ€joÌ£ba yiÌ€í ti bẹ̀rẹ̀, koÌ€ sí gbọ́n mi-síi, omi-ò̀-tóo ni IÌ€pínlẹ̀ Ọ̀yó.Ì£

 

Àwòkọ́ṣe Gómìnà Abíọ́lá Adéyẹmí Ajímọbi ni Kọmísánà fún Ètò ẹ́kọ́ náà ń tẹ̀ lè ìgbà tí Ọ̀jọ̀gbọ́n Solomon Ọláníyọnu ti dé , ni Ètò-ẹ̀kọ́ tí n tẹ̀síwájú ni gbogbo ọ̀nà. Ni ti Họṇrébù Jacob Fúnmi Ògúmọ́lá, tẹ̀tẹ̀ pòpó ti lomi tẹ́lè kí òjò tóó dé ni ọ̀rọ̀ rẹ̀. Kí á tóó yàn án gẹ́gẹ́ bí Alága A-fún-nṣọ́ ní ó ti nífẹ̀ẹ́ sí ètò ẹ́kọ̀; tí ó sí ń ṣe kóríyá fún àwọn akẹ́kọ̀ọ́ ní ìjọba Ìbílẹ̀ Atisbo àti Òkè-Ogún lápapọ̀.

 

Oun ni OluÌ€dásílẹ́ “Ogúnmọ́lá Foundation” tí ó pe aÌ€laÌ€jẹ́ reÌ€ niÌ€  “iÌ€gbé ayé iÌ€rọ̀ruÌ€n fún aÌ€woÌ£n eÌ€niÌ€yaÌ€n mi” Láti oÌ£dún ni ó siÌ€ ti bẹ̀rẹ̀.

Ní ọdún 2012, àti 2013, Ó fún àwọn akẹ́kọ̀ọ́ bí Ọgbọ̀n ní ẹ̀kọ́-ọ̀fẹ́ ní jọba ìbílẹ̀ ATISBO, Ó sì fún àwọn opó ní jọba ìbìlẹ̀ ATISBO, ìla-òòrùn Ṣakí àti Ìwọ̀- Oòrùn Ṣakí ní ẹbùn tó jọjú.

Ní ọdún 2014 yìí, Aké̀kọ̀ọ́ bíi mẹ́rìn-lé-láaàádọ́fà (114 students) káàkiri Ilẹ́-ẹ̀kọ́ sẹ̀kóndírì ní òkè-ògùn ni ó fún ẹ̀bùn èkọ̀ ọ̀fẹ́ yìí, ó sì fún àwọn opó bíí ẹ̀ẹ́dẹ̀gbẹ̀ta ní gbogbo Ìbìlẹ̀ mẹ́wẹ̀ẹ̀wá tí ó wà ní Òkè-Ògùn ní irú ẹ̀bùn yìí kan náà:

Alága yiÌ€í kọ́ yaÌ€aÌ€rá iÌ€kaÌ€wé sí gbogbo ilé-ẹ̀kọ́ sẹ́kọ́ndíriÌ€ ti iÌ€joÌ£ba ní iÌ€joba IÌ€bílẹ̀ ATISBO. Bákan náaÌ€, ógbẹ́  kaÌ€nga-dẹ̀roÌ£ (bole-hole) sí gbogbo aÌ€woÌ£n ilé-ẹ̀kọ́ Sẹ́kọ́ndírí yiÌ€í.

Bẹ́ẹ̀ ló ma ń sÌ£e kóríyá  lóóreÌ€kóóreÌ€ fún aÌ€won ọ̀gá Ilé-ẹ̀kọ́ gbogbo nígbaÌ€ tí wọ́n bá ń loÌ£ síbí aÌ€péro  oÌ£lọ́doÌ£oÌ£dún, aÌ€ti isÌ£ẹ́ miÌ€íraÌ€n tí a oÌ€ le máa kaÌ€ tán leÌ£seÌ£eÌ£seÌ£.

A kíyèsí i wí pé, kò si ohun tí ó le mú kí ènìyàn máa ṣe eléyìí bí kò bà jẹ́ ọmọlúàbí ènìyàn, torí pé ọ̀kan lára ohun tí ẹgbẹ́ yìí ń gbé lárugẹ ni ìwà Ọmọlúàbí, a wòye pè wọ́n yẹ ní ẹni tí ó yẹ, kí á dá lólá.

 

Bẹ́ẹ̀ gẹ́gẹ́ ni ọ̀rọ̀ kábíyeÌ€sí Sọ̀ún ti ilẹ̀ OÌ€gbómọ̀sÌ£ọ́ rí; oÌ€ótọ́ ni wí pé bí iÌ€lú bá ń toÌ€roÌ€, tí ó ń daÌ€gbaÌ€ síi, tí nńkan rere siÌ€ ń seÌ£lẹ̀ níbeÌ£, kí á mọ́ wí pé loĺríire oÌ£ba ni wọ́n ní; AÌ€siÌ€koÌ€ baÌ€bá yiÌ€í  ń tuÌ€baÌ€, ó siÌ€ ń tuÌ€seÌ£, ní agbára EÌ£lẹ́daÌ€á, eÌ£ ó gboÌ€ó, gboÌ€ó gboÌ€ó olúogbó, eÌ£ ó daÌ€gbaÌ€ daÌ€gbaÌ€, olúyẹ̀yẹ̀-nÌ€ tuyẹ̀. EÌ€yí tó gbógboÌ€ógbó tó foÌ£moÌ£ owú sÌ£e ońdeÌ€ sọ́ruÌ€n, omo owú jeÌ£ jeÌ£eÌ£ jeÌ£ kuÌ€ bí abẹ́rẹ́, abẹ́rẹ́ jeÌ£ jeÌ£eÌ£ jeÌ£ kuÌ€ bí iÌ€rú eÌ£sÌ£in.

Adé yòó pẹ́ lórí, ìlẹ̀kẹ̀ yòó pẹ́ lọ́run, ẹ ó fi èrìgì jobì, ẹsin ọba yóò sì jẹko pé.

          Mo kí AÌ€areÌ£ EÌ£gbẹ̀ aÌ€ti gbogbo oÌ£moÌ£ iÌ€gbiÌ€mọ̀ rẹ̀, kú oríire lóniÌ€í, YoruÌ€bá bọ̀; wọ́n ní ojú tí yóoÌ€ ba bá ni kalẹ́, koÌ€ niÌ€í taÌ€árọ̀ yoÌ£ ipin; oríire tí eÌ£ fi bẹ̀rẹ̀ yiÌ€í yóoÌ€ tẹ̀síwájú lágbára oÌ£lórun.

          IÌ€paÌ€dé aÌ€péroÌ€ ti oÌ£dún yiÌ€í aÌ€rá ọ̀tọ̀ ni, bí a bá sÌ£e eré oÌ€koÌ€tó débi tí aÌ€ ń dáraÌ€á konko, eré sÌ£etán tí yoÌ€ó túká ni; ní aÌ€siÌ€koÌ€ tiyín yiÌ€í, aÌ€raÌ€a tuÌ€jẹ̀ ni a ó maa dá; ara yóoÌ€ máa tu gbogbo oÌ£moÌ£ eÌ£gbẹ́ pẹ̀sẹ̀; gbogbgo aÌ€fojúsuÌ€n eÌ£gbẹ́ yóoÌ€ siÌ€ máa jẹ́ sísÌ£e.

          Ní orúkoÌ£ gbogbo oÌ£moÌ£ eÌ£gbẹ́ ní iÌ€pínlẹ̀ ọ̀yọ́, ni moÌ€ ń kí wa káábọ̀ sí iÌ€padé aÌ€péroÌ€ ti oÌ£dún yiÌ€í; Ní agbára EÌ£lẹ́daÌ€á, gẹ́gẹ́ bí Ọ̀jọ̀gbọ́n AkínwuÌ€mí IÌ€sọ̀lá sÌ£e soÌ£ nínú IÌ€wé EwiÌ€i rẹ̀ “AÌ€faÌ€iÌ€mọ̀ aÌ€ti aÌ€woÌ£n aÌ€roÌ€fọ̀ miÌ€íraÌ€n” ó ní:

“KoÌ€ sÌ£éléré ehoro,

Kò sólókìtì ìjímèrè,

Kò sírú u kánún láárin òkúta,

KoÌ€ sírú iyọ̀ léépẹ̀   

Eégun tó le jó bíi lébe oÌ€ sí mọ́”

Kò tún sí okùn mìíran nígbó mọ́

Báa bá ti yọwọ́ ọ kán-ànrán-jangban

Kò tún ṣegbẹ́ẹ mìíran

Tí ìmọ̀ wọn le jọ tí yóò sì sọ̀kan,

Bí ẹgbẹ́ Akọ́mọlédè àti Àṣà Yorùbá

Lọ́lá Ẹlẹ́dàá; Iwájú ni ojúgun ún gbé

Iwájú ni Èdè Yorùbá yóò máa lọ. Àṣẹ.

 

Tóò, bí ọbẹ̀ kò tilẹ̀ dùn, à maa torí àníyàn jẹẹ́, gbogbo kùdìẹkudiẹ tó bá kù nínú ètò wa, ẹ bá wa fi ṣosùn, kí ẹ fi kunra; A kìí mọ ọ́n gún mọ̀ ọ́n tẹ̀ kí iyán ewùrà má léenmọ́; mo gbàgbọ́ wí pé tí tí a ó fi parí àpérò yìí, ire lojú owó ó rí, iré la ó fojú wa rí o.

Ẹ ṣeé, Ẹ káàbọ̀.

Reviewed Publications

  • Ise Yoruba - Reviewed by Sobande Seyi
  • Asa ati Ede - Reviewed by Adedigba Sylvester
  • View All →

    Subscribe to Our
    Newsletter

    Quotable Quote

    The only person that is educated is the one that has learned how to learn and change. - Carl Rogers

    OÌ£wóÌ£ oÌ£moÌ£dé kò tó peÌ£peÌ£ ti àgbàlagbà kò woÌ£ kèrègbè

     

    Ewé kì í bóÌ£ lára igi kó ni igi lára ----- the dropping of a leaf off a tree presents no burden to the tree.

    © 2026 Egbe Akomolede ati Asa Yoruba Naijiria. All Rights Reserved.