...fostering unity

among Yoruba people

...promoting the

teaching of Yoruba culture

...celebrating the

values of Yoruba

ẸGBẸ́ AKỌ́MỌLÉDÈ ÀTI ÀṢÀ YORÙBÁ, NÀÌJÍRÍÀ

Mo júbà Ọlọ́run Olódùmarè. Mo júbà gbogbo ẹ̀yin àgbààgbà Ẹgbẹ́ Akọ́mọlédè lọ́kùnrin àti lóbìnrin.

Mo kí ẹ̀yin ìgbìmọ̀ tí ẹ ti ń tùkọ̀ ẹgbẹ́ yìí bọ̀ ṣaájú àkókò yìí.

Ayọ̀ àti ìdùnnú ìgbìmọ̀ wa ni láti rí ibi tí àwọn aṣaájú wa tukọ̀ ẹgbẹ́ yìí dé pẹ̀lú ìlérí àtìlẹyìn gbogbo ọmọ ẹgbẹ́ láti ṣàtìlẹ́yìn ìtẹ̀síwájú rere fún ìgbìmọ̀ wa.

Mo ṣèbà gbogbo ọmọ Ẹgbẹ́ Akọ́mọlédè lọ́kùnrin àti lóbìnrin jákè-jádò àgbàláayé fún ìnáwó-nára pẹ̀lú àtìlẹyìn fún Ẹgbẹ́ yìí. Kò ní í sú waá ṣe o.

Lóòótọ́, Ọlọ́run àti ìfọwọ́sowọ́pọ̀ ẹgbẹ́ yìí yàn mí gẹ́gẹ́ bí Ààrẹbìnrin kejì láti tukọ̀

egbẹ́ wa yìí síwájú. Mo wá fi àsìkò yìí rọ̀ wá láti jọ̀wọ́ fọwọ́sowọ́pọ̀ mú àkọ̀tun ìtẹ̀síwájú bá ẹgbẹ́ wa.A o máa fi ọ̀rọ̀ wa lọ ẹ̀yin àgbà. Mo si gbàdúrà  fún wa pé Ọlọ́run yóò ran ẹ̀yin àgbà wa lọ́wọ́ láti tọ́ wa sọ́nà bí ó ti tọ́ àti bí ó ti yẹ,láti mú èròǹgbà wa ṣẹ fún ìyìnlógo Ọlọ́run àti ìdàgbàsókè Ẹgbẹ́ Akọ́mọlédè àti Àṣà Yorùbá Nàìjíríà.

Ayọ̀,ìbùkún àti ojúrere Olódùmarè kò ní í dásẹ̀ lọ́ọ̀dẹ̀ gbogbo ọmọ ẹgbẹ́ pátá.

Ire o!!!

Díákónì Ọmọ́wùmí aya Fálẹ́yẹ

Ààrẹ Ẹgbẹ́ 

Gẹ́gẹ́ bí àwọn Onígbàgbọ́, a-tẹ̀lé-Kristi ti, ọkàn nínú àwọn orin tí Olóògbé Àlúfà Àgbà kan tí ó jẹ́ ọmọ Ẹ̀gbá, tí a si ńpè ní Josiah Jesse Ransome-Kuti ti kọ̣ ní ohùn orin ti ilẹ̀ wa ní ọ̀pọ̀lọpọ̀ ọdún sẹ́yìn báyìí pé:

Láàarin Osù Ogún Ọdún, Arákùnrin kan wà ní Ìbàdàn tí ó ti ńṣe iṣẹ́ Olùkọ́ni ní Ìbàdàn Boys’ High School, tí ó wà ní Òke Bọ́là ní Ìbàdàn, sùgbọ́n tí ó ti fi iṣẹ́ Olùkọ́ni sílẹ̀ tí ó sì ńṣe iṣẹ́ Olùkọ̀wé lóríṣìíríṣìí ọ̀nà láti ọ̀nà láti ran àwọn ọmọ Ilé-Ẹ̀kọ́ Gíga lọ́wọ́ nínú èdè Yorùbá. Nínú àwọn ìwé tí ó kọ nígbà náà ni “Ìgbáradì fún Ìdánwò Oníwèé Mẹ́wàá”  tí a mọ̀ sí West African Examination Council’s School Certificate tàbí General Certificate Examination (Ordinary Level).

N kò pàdé arákùnrin yìí rí, n kò sì mọ́ ọ́ rí, sùgbọ́n ó jẹ́ ohun ìyàlẹ́nu fún mi nígbà tí ó wá bá mi ní Ilé Ẹ̀kọ́  Gíga tí mo ṣẹ̀ṣẹ̀ bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ nígbà náà tí à ń pè ní Èyínnì High School, Ibadan. Olóyè J.A. Ọlá Ọdẹ́bìyí, tí ó ti fi ìgbà kan jẹ́ Mínísítà ní Ìjọba Ìwọ̀ Oòrùn lábẹ́ Olóyè Ọbáfẹ́mi Awólọ́wọ̀ ni ó dá Ilé-Ẹ̀kọ́ Gíga yìí sílẹ̀.

Mo ní n kò mọ ẹni tí ó tọ́ka mi sí arákùnrin yìí pé mo ní ìfẹ́ èdè Yorùbá tó bẹ̀ẹ̀ nígbà náà. Àwọn Àgbà tàbí Ògbólógbòó Olùkọ́ni bíi èmi sáà wà ní Ìlú Ìbàdàn nígbà náà, sùgbọ́n ó dàbí ẹni pé ẹ̀mí Baba wa Odùduwà  ní ó darí  rẹẹ̀ sí mi.

Ó máa ń pàrà ọ̀dọ̀ mi gẹ́gẹ́ bíi ẹni tí ó ní ìgbàgbọ́ nínú rẹẹ̀ pé ó le ran òun lọ́wọ́ nínú èrò tí òun fẹ́ gbé jáde nipa Èdè Yorùbá nígbà náà.

Bíi ojoojúmọ́ ni ó máa ń wá tí ó sì ń rọ̀ mí láti dìde sí iṣẹ́ yìí láti dá ẹgbẹ́ Olùkọ́ni ní Èdè Yorùbá sílẹ̀ ní Ìbàdàn.

Nígbà tí mo fi ojú inú wo ọ̀rọ̀ náà, mo wòye pé iṣẹ́ ńlá ni yóò jẹ ní Ìlú ńlá bíi Ìbàdàn yìí. Sùgbọ́n nígbà tí ó tún dé mo ní kí ó wá fún èsì lẹ́hìn ọ̀sẹ̀ méjì, Ó gbọ́ ó sì lọ. Kò jẹ́ kí àsìkò yẹn pé kí ó tó tún padà wá, sùgbọ́n, èmi náà ti múra èsì tí n ó fún un sílẹ̀.

Read More →

Reviewed Publications

 • Ise Yoruba - Reviewed by Sobande Seyi
 • Asa ati Ede - Reviewed by Adedigba Sylvester
 • View All →

  Member Login

  Username:
  Password:
   

  Click here to register

  Webmail

     

  Follow Us

     

  Subscribe to Our
  Newsletter

  Quotable Quote

  The only person that is educated is the one that has learned how to learn and change. - Carl Rogers

  Ọwọ́ ọmọdé kò tó pẹpẹ ti àgbàlagbà kò wọ kèrègbè

   

  Ewé kì í bọ́ lára igi kó ni igi lára ----- the dropping of a leaf off a tree presents no burden to the tree.

  © 2021 Egbe Akomolede ati Asa Yoruba Naijiria. All Rights Reserved.